Deuteronomy 25:17-19

17 aRántí ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. 18Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 19Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Amaleki rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.

Copyright information for YorBMYO